Tí a bá wò bí tí àwọn ọkọ̀ ojú irin oní iré gíga ṣe sáré gbà, tí iré yìí sì máa yá ẹni lẹ́nu ; àṣirí tó wà lẹ́yìn ẹ ni, ẹ̀rọ àmóhun ṣiṣẹ́ oní ìgbì iná alàìdúró.
Kìí ṣe inú ọkọ̀ ojú irin nìkan ni a lò ó, ẹ̀rọ amóhun ṣiṣẹ́ (ẹ̀ńjìnì ) yìí náà ni a máa ń lò nínú àwọn ẹ̀rọ ìfọ́ṣọ, ẹ̀rọ ìlọ̀ta, ẹ̀rọ ìgbénisókè, ìgbéhunsókè àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ẹ̀rọ yìí náà ni a tún máa ń pè ni ẹ̀rọ amóhun ṣiṣẹ́ oní ìgbì iná DC ( ìgbì iná alàìdúró ).
Báwo ni a ṣe rọ ọ́ gbà ?
Ohun èlò àkọ́kọ́ tí a lò ni onígún mẹ́rin tí a pè ní PQRS a ṣé é pẹ̀lú okun iná ẹdẹ àdádó tí àwọn èyà ẹ mẹ́rẹ́rin sì jẹ́ PQ, RS, PR, QS. Α gbé é sí àárin òòfà méjì lọ́nà ti onígún mẹ́rin yìí sì pọ̀gbà pẹ̀lú agbára òòfà agbègbè náà. Α so àwọn èbúté ẹ méjì mọ́ orúka tí a gé sí méjì lọ́gbọgba, àwọn ẹ̀yà méjèjì ni X, Y, kí wọ́n má bá kan ara wọn, a ti ọpá igi kan bọ́ àárin wọn : Àwòrán 1. Α wá so àwọn ìgbalẹ̀ méjì B1, B2 mọ́ àwọn ẹ̀yà orúka X, Y wọ̀nyìí. Lẹ́yìn náà ni a wá so àwọn ìgbalẹ̀ méjèjì mọ́ amúnáwá oní ìgbì iná alàìdúró.
Báwó ni gbogbo èyí ṣe ń ṣiṣẹ́ gbà ?
Ìgbì iná tó bá kúrò nínú amúnáwá alàìdúró, yóò wọlé gbà ìgbálẹ̀ B1, yóò sì gbà inú onígún mẹ́rin PQRS tí yóò sì wá jáde gbà ìgbálẹ̀ B2. Tí a bá wò Àwòrán 2, a ó ri pé agbára iṣiṣẹ́ kan ò sí lórí àwọn èyà PQ , RS nítorí wọ́n pọ̀gbà lọ́nà kannáà pẹ̀lú agbára òòfà, ti wón ò sì lè pàde ara. Àmọ́ àwọn ẹ̀yà PR, QS dábùú agbára agbègbè òòfà náà. Orí ẹ̀yà PR ìgbì iná àti agbára òòfà wọ́n á ṣẹ̀dá agbára ìṣiṣẹ́ tí yóò sì dárí sílẹ̀, ìṣẹ̀dá agbára ìṣiṣẹ́ yóò tún wáyé lórí ẹ̀yà QS nítorí ohun náà wà nínú agbára òòfà tí ìgbì iná sì gbà inú ohun náà àmọ́ agbára ìṣiṣẹ́ á dárí sókè, onígún mẹ́rin yìí yóò wá bẹ̀rẹ̀ sí máa yí ní ọ̀nà alòdì sí ọ̀nà ìyí ọwọ́ aago.
Tí onígún mẹ́rin bá yí dé igún 90º, àwọn ìgbalẹ̀ B1 àti B2 wọ́n á kúro lára àwọn ẹ̀yà orúka wọ̀nyìí, ìgbì iná á dúró láti máa gbà inú ẹ̀yà onígún mẹ̀rin, àwọn ẹ̀yà QP àti RS wọ́n kò níí tún sí lábẹ̀ agbára ìṣiṣẹ́ mọ́, èyí á túmọ̀ sí pé onígun ò níí yí mọ́, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀, onígún ò lè dúró lójíjì, yóò tún yí diẹ̀ fikun: Àwòrán 3, ibẹ̀ ni àwọn ìgbalẹ̀ wọ̀nyìí, wọ́n á tún so mọ́ àwọn ẹ̀yà orúka, tí ìgbì iná á tún padà wọ inú onígún mẹ̀rin tí yóò tún wá yìí dé igún 180º, níbẹ̀ ìdárí ìgbì iná PR àti QS wọ́n á yí padà, agbára ìṣiṣẹ́ RS á lọ sílẹ̀, ti PQ á lọ sókè, tí onígún mẹ́rin á tún yí dé igún 270º, níbẹ̀ àwọn ìgbalẹ̀ wọ́n á tún kúrò lára àwọn ẹ̀yà orúka tí ìgbì iná á tún dúró láti máa wọ inú onígún mẹ́rin bí ti àtẹ̀yìn wá ìdúró yìí kò lè wáyé lójíjì onígún yì á tún yí díẹ̀ fikun tí àwọn ìgbalẹ̀ wọ́n á tún padà so mọ́ àwọn ẹ̀yà orúka, onígún mẹ́rin á tún yìí dé igún 360º tí kò sì níí dúró lójíjì bákannáà, tí onígun á sì máa wá yìí lọ bẹ́ẹ̀.
Ìyára ẹ̀rọ yìí so mọ́ nǹkan púpọ̀ :
Tí àrunpọ̀ bá pọ̀ sì, ìyára a máa lọ sókè sí.
Tí agbára iná bá lọ sókè, ìyára á tún máa lọ sókè.
Tí agbára òòfà bá lọ sókè, ìyára yìí á tún máa gbooro.
Àmọ́ tí a bá fẹ́ rọ ògídi ẹ̀rọ àmóhun ṣisẹ́ alágbára , a yóò mú àwọn àrunpọ̀ tí a á sì fi wọ́n yí kúró irin ká, a á wá kó àwọn àrunpọ̀ wọ̀nyìí sí àárin àwọn òòfà méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, a á so àwọn àrunpọ̀ mọ́ agbára iná, tí ìgbì iná bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn nínú àwọn àrunpọ̀ wọ̀nyìí irin kúró á bẹ̀rẹ̀ sí máa yí, tí opá tí a so mọ́ ọ́ pàápàá á bẹ̀rẹ̀ sí máa yí, báyìí agbára iná tí a fún ẹ̀rọ yì á padà dí agbára ìṣiṣẹ́.